Sign in
Sign in
Sign in
Select Language
058

Al-Mujadila 58:13 ااشفقتم ان تقدموا بين يدي نجواكم صدقات فاذ لم تفعلوا وتاب الله عليكم فاقيموا الصلاة واتوا الزكاة واطيعوا الله ورسوله والله خبير بما تعملون ١٣

58:13
ءَأَشۡفَقۡتُمۡ
أَن
تُقَدِّمُواْ
بَيۡنَ
يَدَيۡ
نَجۡوَىٰكُمۡ
صَدَقَٰتٖۚ
فَإِذۡ
لَمۡ
تَفۡعَلُواْ
وَتَابَ
ٱللَّهُ
عَلَيۡكُمۡ
فَأَقِيمُواْ
ٱلصَّلَوٰةَ
وَءَاتُواْ
ٱلزَّكَوٰةَ
وَأَطِيعُواْ
ٱللَّهَ
وَرَسُولَهُۥۚ
وَٱللَّهُ
خَبِيرُۢ
بِمَا
تَعۡمَلُونَ
١٣
Ṣé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa ti ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Continue Reading

Read Tafsir

Ibn Kathir (Abridged)

The Order to give Charity before One speaks to the Prophet in private

Allah commanded His believing servants, when any of them wanted to speak with Allah's Messenger ﷺ in secret, to give away charity beforehand so that his charity cleanses and purifies him and makes him worthy of having a private cou

…

The Order to give Charity before One speaks to the Prophet in private

Allah commanded His believing servants, when any of them wanted to speak with All

…
More Tafsirs

Read in Context

Chapter 58, Page 544, Juz 28

5. Dájúdájú àwọn tó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, A óò yẹpẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe yẹpẹrẹ àwọn tó ṣíwájú wọn. A kúkú ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́. 6. Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, àwọn sì gbàgbé rẹ̀. Allāhu sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan. 7. Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. 8. Ṣé o kò rí àwọn tí A kọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ fún, lẹ́yìn náà tí wọ́n tún padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Wọ́n ń bára wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Nígbà tí wọ́n bá sì dé ọ̀dọ̀ rẹ, wọn yóò kí ọ ní kíkí tí Allāhu kò fi kí ọ. Wọ́n sì ń wí sínú ẹ̀mí wọn pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Allāhu jẹ wá níyà lórí ohun tí à ń wí (ní ìkọ̀kọ̀)!” Iná Jahanamọ máa tó wọn. Wọ́n máa wọ inú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú. 9. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Ẹ bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. 10. Dájúdájú ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (burúkú) ń wá láti ọ̀dọ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n nítorí kí ó lè kó ìbànújẹ́ bá àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá wọn àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé. 11. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fún yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: “Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere).” Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 12. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá bá Òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ, ẹ fi ọrẹ títa ṣíwájú ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín. Ó sì fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Tí ẹ ò bá sì rí (ọrẹ), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 13. Ṣé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa ti ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Notes and Reflections

You do not have any notes or reflections on this verse.

Notes placeholders

Stay Connected to the Quran ❤️

Short meaningful reminders to reset, reflect and stay connected to the Quran.

Read, Listen, Search, and Reflect on the Quran

Quran.com is a trusted platform used by millions worldwide to read, search, listen to, and reflect on the Quran in multiple languages. It provides translations, tafsir, recitations, word-by-word translation, and tools for deeper study, making the Quran accessible to everyone.

As a Sadaqah Jariyah, Quran.com is dedicated to helping people connect deeply with the Quran. Supported by Quran.Foundation, a 501(c)(3) non-profit organization, Quran.com continues to grow as a free and valuable resource for all, Alhamdulillah.

Navigate
Home
Quran Radio
Reciters
About Us
Developers
Product Updates
Feedback
Help
Donate
Our Projects
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Non-profit projects owned, managed, or sponsored by Quran.Foundation
Popular Links
Duas from the Quran
Quran Verse of the Day
Ayatul Kursi
Yaseen
Al Mulk
Ar-Rahman
Al Waqi'ah
Al Kahf
Al Muzzammil
SitemapPrivacyTerms and Conditions
© 2026 Quran.com. All Rights Reserved
Contribute