Sign in
Sign in
Sign in
Select Language
016

An-Nahl 16:105 انما يفتري الكذب الذين لا يومنون بايات الله واولايك هم الكاذبون ١٠٥

16:105
إِنَّمَا
يَفۡتَرِي
ٱلۡكَذِبَ
ٱلَّذِينَ
لَا
يُؤۡمِنُونَ
بِـَٔايَٰتِ
ٱللَّهِۖ
وَأُوْلَٰٓئِكَ
هُمُ
ٱلۡكَٰذِبُونَ
١٠٥
Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu ló ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni òpùrọ́.
Continue Reading

Read Tafsir

Ibn Kathir (Abridged)

الَّذِينَ لاَ يُؤْمِنُونَ بِآيَـتِ اللَّهِ

(Verily, those who do not believe in Allah's Ayat,) Allah will not guide them, and theirs will be a painful punishment, meaning, the disbelievers and heretics who are known to the people as liars. The Messenger Muhammad ﷺ, on the other hand, was the most hon

…

الَّذِينَ لاَ يُؤْمِنُونَ بِآيَـتِ اللَّهِ

(Verily, those who do not believe in Allah's Ayat,) Allah will not guide them, and theirs will be a painful

…
More Tafsirs

Read in Context

Chapter 16, Page 279, Juz 14

101. Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀. 102. Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ló sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ pẹ̀lú òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí. 103. A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan ló ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń darí al-Ƙur’ān kọ ní ọ̀nà òdì (pé ó ń kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí. 104. Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn. 105. Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu ló ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn gan-an sì ni òpùrọ́. 106. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣí igbá-àyà rẹ̀ sílẹ̀ fún àìgbàgbọ́, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn. 107. Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́. 108. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni afọ́núfọ́ra. 109. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run. 110. Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́).

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Notes and Reflections

You do not have any notes or reflections on this verse.

Notes placeholders

Stay Connected to the Quran ❤️

Short meaningful reminders to reset, reflect and stay connected to the Quran.

Read, Listen, Search, and Reflect on the Quran

Quran.com is a trusted platform used by millions worldwide to read, search, listen to, and reflect on the Quran in multiple languages. It provides translations, tafsir, recitations, word-by-word translation, and tools for deeper study, making the Quran accessible to everyone.

As a Sadaqah Jariyah, Quran.com is dedicated to helping people connect deeply with the Quran. Supported by Quran.Foundation, a 501(c)(3) non-profit organization, Quran.com continues to grow as a free and valuable resource for all, Alhamdulillah.

Navigate
Home
Quran Radio
Reciters
About Us
Developers
Product Updates
Feedback
Help
Donate
Our Projects
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Non-profit projects owned, managed, or sponsored by Quran.Foundation
Popular Links
Duas from the Quran
Quran Verse of the Day
Ayatul Kursi
Yaseen
Al Mulk
Ar-Rahman
Al Waqi'ah
Al Kahf
Al Muzzammil
SitemapPrivacyTerms and Conditions
© 2026 Quran.com. All Rights Reserved
Contribute