Sign in
Sign in
Sign in
Select Language
040

Ghafir 40:13 هو الذي يريكم اياته وينزل لكم من السماء رزقا وما يتذكر الا من ينيب ١٣

40:13
هُوَ
ٱلَّذِي
يُرِيكُمۡ
ءَايَٰتِهِۦ
وَيُنَزِّلُ
لَكُم
مِّنَ
ٱلسَّمَآءِ
رِزۡقٗاۚ
وَمَا
يَتَذَكَّرُ
إِلَّا
مَن
يُنِيبُ
١٣
Òun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
Continue Reading

Read Tafsir

Ibn Kathir (Abridged)

The Regret of the Disbelievers after They enter Hell

Allah tells us that the disbelievers will feel regret on the Day of Resurrection, when they enter Hell and sink in the agonizing depth of fire. When they actually experience the unbearable punishment of Allah, they will hate themselves with the utm

…

The Regret of the Disbelievers after They enter Hell

Allah tells us that the disbelievers will feel regret on the Day of Resurrection, when they enter

…
More Tafsirs

Read in Context

Chapter 40, Page 468, Juz 24

10. Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): “Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́.” 11. Wọ́n wí pé: “Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?” 12. (Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi. 13. Òun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà). 14. Nítorí náà, ẹ pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un. àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀. 15. (Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà. 16. Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): “Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní?” Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni. 17. Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́. 18. Àti pé ṣèkìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó súnmọ́ (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde). Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí. 19. (Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́. 20. Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Notes and Reflections

You do not have any notes or reflections on this verse.

Notes placeholders

Stay Connected to the Quran ❤️

Short meaningful reminders to reset, reflect and stay connected to the Quran.

Read, Listen, Search, and Reflect on the Quran

Quran.com is a trusted platform used by millions worldwide to read, search, listen to, and reflect on the Quran in multiple languages. It provides translations, tafsir, recitations, word-by-word translation, and tools for deeper study, making the Quran accessible to everyone.

As a Sadaqah Jariyah, Quran.com is dedicated to helping people connect deeply with the Quran. Supported by Quran.Foundation, a 501(c)(3) non-profit organization, Quran.com continues to grow as a free and valuable resource for all, Alhamdulillah.

Navigate
Home
Quran Radio
Reciters
About Us
Developers
Product Updates
Feedback
Help
Donate
Our Projects
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Non-profit projects owned, managed, or sponsored by Quran.Foundation
Popular Links
Duas from the Quran
Quran Verse of the Day
Ayatul Kursi
Yaseen
Al Mulk
Ar-Rahman
Al Waqi'ah
Al Kahf
Al Muzzammil
SitemapPrivacyTerms and Conditions
© 2026 Quran.com. All Rights Reserved
Contribute