Sign in
Sign in
Sign in
Select Language
012

Yusuf 12:68 ولما دخلوا من حيث امرهم ابوهم ما كان يغني عنهم من الله من شيء الا حاجة في نفس يعقوب قضاها وانه لذو علم لما علمناه ولاكن اكثر الناس لا يعلمون ٦٨

12:68
وَلَمَّا
دَخَلُواْ
مِنۡ
حَيۡثُ
أَمَرَهُمۡ
أَبُوهُم
مَّا
كَانَ
يُغۡنِي
عَنۡهُم
مِّنَ
ٱللَّهِ
مِن
شَيۡءٍ
إِلَّا
حَاجَةٗ
فِي
نَفۡسِ
يَعۡقُوبَ
قَضَىٰهَاۚ
وَإِنَّهُۥ
لَذُو
عِلۡمٖ
لِّمَا
عَلَّمۡنَٰهُ
وَلَٰكِنَّ
أَكۡثَرَ
ٱلنَّاسِ
لَا
يَعۡلَمُونَ
٦٨
Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Continue Reading

Read Tafsir

Ibn Kathir (Abridged)

Ya`qub orders His Children to enter Egypt from Different Gates

Allah says that Ya`qub, peace be upon him, ordered his children, when he sent Binyamin with them to Egypt, to enter from different gates rather than all of them entering from one gate. Ibn `Abbas, Muhammad bin Ka`b, Mujahid, Ad-Dahhak Qat

…

Ya`qub orders His Children to enter Egypt from Different Gates

Allah says that Ya`qub, peace be upon him, ordered his children, when he sent Binyamin w

…
More Tafsirs

Read in Context

Chapter 12, Page 243, Juz 13

63. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.” 64. Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.” 65. Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí i pé wọ́n ti dá owó-ọjà wọn padà fún wọn. Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).” 66. Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).” 67. Ó tún sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (kan) àfi ti Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.” 68. Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Notes and Reflections

You do not have any notes or reflections on this verse.

Notes placeholders

Stay Connected to the Quran ❤️

Short meaningful reminders to reset, reflect and stay connected to the Quran.

Read, Listen, Search, and Reflect on the Quran

Quran.com is a trusted platform used by millions worldwide to read, search, listen to, and reflect on the Quran in multiple languages. It provides translations, tafsir, recitations, word-by-word translation, and tools for deeper study, making the Quran accessible to everyone.

As a Sadaqah Jariyah, Quran.com is dedicated to helping people connect deeply with the Quran. Supported by Quran.Foundation, a 501(c)(3) non-profit organization, Quran.com continues to grow as a free and valuable resource for all, Alhamdulillah.

Navigate
Home
Quran Radio
Reciters
About Us
Developers
Product Updates
Feedback
Help
Donate
Our Projects
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Non-profit projects owned, managed, or sponsored by Quran.Foundation
Popular Links
Duas from the Quran
Quran Verse of the Day
Ayatul Kursi
Yaseen
Al Mulk
Ar-Rahman
Al Waqi'ah
Al Kahf
Al Muzzammil
SitemapPrivacyTerms and Conditions
© 2026 Quran.com. All Rights Reserved
Contribute